Ohun èlò Ìwé ìtumọ̀ Yorùbá Sípáníṣì
Ìwé ìtumọ̀ ni ju ọ̀rọ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ti a ti ṣe àtúnṣe lati èdè nípasè àwọn onímọ̀ èdè méjeèjì. A si lo àmì ohùn tó pé ye fún èdè kọọkan pẹ̀lú ìbójutó láti ọwọ́ ólùkọ́ni eléde Yorùbá.
Ìwé ìtumọ̀ yìí yio rán ní lọ́wọ́ fún ìwadí ni èdè méjeèji , yio si tún wúlo fún álífàbẹtì èdè Yorùbá ati ọ̀rọ̀ pipe bi apẹẹrẹ gbólóhùn ọ̀rọ̀, nọ́mbà,ìtàn àti ìmọ̀ bí a ṣè le ṣe àtúnpín ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bi ohun àfojúúsí
Ni àfikún, wa á lé gbọ ọ̀rọ̀ pipe gìdì lati ẹnu onímọ̀ èdè Yorùbá
lọ́wọ́lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ìwé itumọ Yorùbá Sípáníṣì ń ṣe iwadìí láti le ṣe afikún ọ̀rọ̀ tuntun si ẹ̀ro ayélujára
Èỵ à ohun èlò
Ìdí mẹfà ti a fin lo ohun èlò ìwé ìtumọ Yorùbá Sípáníṣì
Ìwé ìtumọ ayelujara àkọ̀kọ̀
Ìwé ìtumọ Yorùbá Sípáníṣi
Ti a ṣe iṣẹ rẹ lati ọwọ awọn amòye Yorùbá ni ìlú NaijiriaỌ̀rọ̀ to leẹgbẹ̀rún lọnà ọgbọ̀n
Yorùbá Sípáníṣi - Sípáníṣi Yorùbá
A tún fi Yorùbá atijọ́ ti a ko lo mọ si inu rẹAmi ohun
Èdè àtilẹ̀bá
Ami ohun ti awọn amòye Yorùbá ṣe atunṣe rẹNomba èdè Yorùbá
Nomba
Ọ̀nà ti o to lati kọ̀ ọ́ ati lati pè éGbólóhùn ọ̀rọ̀ to wọ́pò
Ìkọsílè
Àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ ti a ń lo ju ni ojoojúmọ́ ati bi a ṣe ń pè éOhùn èdè Yorùbá
Ohun
Àwọn elédè Yorùbálati ilu Naijiria ti pèsè ohun èdè náàẸ̀ya ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Irin àjò nípasé ìwé ìtumọ̀ Yorùbá ati àbùdà rẹ. Ninu ohun èlo ìwé ìtumọ Sípáníṣì, a o ri ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bìí:
Èdè Yorùbá – Yorùbá Language
Èdè Yorùbá jẹ́èdè kan láti Ìwọ̀Oòrùn Áfíríkà, bẹẹ, o si jẹ ẹ̀yà ede Benué-Congo. Nàìjíríà ni wọ́n ti ń sọ èdè náà, ó sì jẹ́ọ̀kan lára àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ni wọ́n tún ń sọ ọ́gẹ́gẹ́bí èdè abínibí ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Benin àti Togo. Ní òde ilẹ̀Áfíríkà, a lè rí àwọn tó ń sọ èdè Yorùbá ní Cuba, Brazil, Puerto Rico, United States àti Trinidad àti Tobago láàárín àwọn orílẹ̀-èdè Látìn Amẹ́ríkà yòókù. Orúkọ ìbílẹ̀èdè yii ni èdè Yorùbá tí ó sì ní nǹkan bí ọgọ́rin mílíọ̀nù àwọn olùsọ èdè káàkiri àgbáyé. O jẹ ọkan ninu awọn ede pataki julọ ni Afirika. Yorùbá gẹ́gẹ́ bi ọro jẹ édè gbajumọ ti o si jẹ akọsilẹ.

Ìwé ìtumọ̀ Yorùbá àkọ́kọ́
Ni ọdún 1819 ni ìjọba Àṣánti ti a mọ̀ sí Ghana loni, a tẹ ìwé Yorùbá jáde la kọ́kọ́. Ìwé yìí kún fún fokabúlárì kékeèké láti ọwọ́ òsélú. Bíritikó Thomas Edward ti n gbeni ìlú Áṣanti. Síbẹ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn ọdún diẹ, elédè Yorùbá Samueli Crowrher , ẹrú ti o gba òmìnira ti o si ni ànfaàní ilé ẹ̀kọ́, o tẹ ìwé gírámá èdè Yorùbá àkọ́kọ́ jade. Samueli tẹ̀dó si Abẹ́okuta ti n ṣe ipinle Ògùn ni si . Ni ọdún 1843, a tẹ ìwé ìtumọ̀ èdè Yorùbá jade lati ọwọ Samueli Crowther. Ni ọdun 1852, a tẹ ìwé miran jade lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ò isẹ́ àti àtúnṣe. Ìwé yi jẹ atọ́nà fun iwadi ati ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá fun ọpọlọpọ ọdún. Lẹ́yìn diẹ ni ọdun 1911 a tẹ ìwẹ́ ìtumọ èdè gẹẹsi si Yorùbá jáde, olùsọ́ àgbà , E.J Sówandẹ̀ lo ṣe alá bojuto rẹ

Screen shots
A tour through the Spanish Yorùbá dictionary.
Kíni ìdí tí a fi dá ohun èlò yìí?
Láti ìgbá ti mo ti ń ṣe iwadi ifa oriṣa ni mo ti mọ̀ pé ìmọ̀ èdè Yorúbà ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ bi ìpínlẹ̀ fún ẹ̀kọ̀ àsà ati ìsèmbáyé.
Àwọn ìwé àṣe ti a gbẹ́kẹlè ni ilu Sípánia ṣọ̀wọ́n láti rí, bẹ́ẹ̀ àwọn ìwé pélébé àtọwọ́dọ́wọ́ kò ní àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àmì ohùn to péye láti le fún ni ní ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ dáàdáà. A ṣe ìwé ìtumọ́ yìí fún ánfáàní àwọn to ni fẹ sí kíkọ́ èdè Yorùbá. Yí ò sì wúlò pàpà jùlọ fún àwọn onífá òrìṣà, nítorí yóò pèsè ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó dájú àti bi a se n pè e. Nítorí náà la ṣe wá àtìlẹyìn àwọn elédè Yorùbá, kí a ba lè gbọ́ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìtumọ tó pé ye ayẹyẹ ìfá – òrìṣà.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ìdàgbàsókè Emeyé ń tẹ̀ si wájú pẹ̀lú iwadìí àti àtúnṣe ọ̀rọ̀ fún ohun èlò ìwé ìtumọ̀ Sípáníṣì Yorùbá – Yorùbá Sípáníṣì ní bi tí a ó ti rí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè Yorùbá nínù àpoti ìsúra.
Erick Mora Babalawo ìmòye ifá – òrìṣà
A kàn sí ìwé ìtàn
Ẹgbẹ́ Emeyé
Erick Mora Carbó
Oníṣé ohun èlo olùyàwòran àti olùgbéjáde ayélujára. Babaláwo. Kúba – Sípéénì.
Rosalía López Aboal
Pìrògírámà, ìsàkósó àpótí ìsúra.
Sípéénì
Abiodun Samuel Adebowale
Olùdámọ̀ràn nínu akóonu èdè Yorùbá
Iléṣà – Ọ̀ṣun, Nàijíríà
Yilian Loreta Berguery Ricardo
Ṣíṣàtunkọ ìgbéróyìn jáde.
Kúba
Oluwakemi Linda Adeolu
Olùkọ́ èdè Yorùbá. Ohùn èlò.
Ado Ekiti – Nàijíríà
Juan Jesus Cilla Ugarte
Olùgbéjáde ohùn èlò.
Sípéénì
Cristian Perez Corral
Olùgbéjáde ohùn èlò.
Sípéénì
Emmanuel Mesole
Olùkọ́ èdè Yorùbá.
Olùdámọ̀ràn.
Ìkosì – Kétu, Lagos, Nàijíríà